Aaaah ah Ye a ma de o, a ma de o A wa n kilọ funra wa ni o Ye a ma de o, orẹ a tun de o Ẹ jẹ a ṣ'otitọ fun'rawa o Ye a ma de o, a ma de o A wa n kilọ funra wa ni o Ye a ma de o, orẹ a tun de o Ẹ jẹ a ṣ'otitọ fun'rawa o Iwọ gbẹsin sori, gbogbo ara ilu ti wa d'ẹlẹṣẹ loju rẹ Ẹyin gbẹsin leri, ẹ wa n paniyan l'orukọ Ọlọrun loke Ṣe iwọ ti gbagbe o Pe Ọlọrun ọba, Oluwa ifẹ ni kii korira Se ẹyin ti gbagbe o Pe Eledumare alagbara Ko le gbeja ara re, ye e-e Ye a ma de o, a ma de o A wa n kilọ funra wa ni o Ye a ma de o, orẹ a tun de o Ẹ jẹ a s'otitọ fun'rawa o Iwọ depo ọla, o wa n ṣiwa hu, o ti gbagbe orisun O n jaye olowo, ọmọde ilu n wọnu akitan kebi ma pa wọn o Ko le s'alaafia ninu ilu binu ara ilu o ba dun Ko le s'alaafia ọrẹ f'olowo fun talaka Ba o ba ṣ'otitọ ni'jọba o Ye a ma de o, a ma de o A wa n kilọ funra wa ni o Ye a ma de o, orẹ a tun de o Ẹ jẹ a ṣ'otitọ fun'rawa o Ọrẹ otitọ ṣọwọn o Ife otitọ ṣọwọn ye Oo le gbara l'ẹnikankan o Wọn a ba ẹ jẹ o, wọn a ba ẹ mu o To ba yẹyin pada, wọn a sọrọ ẹ ni buruku Wọn a ba ẹ logba, wọn a ba ẹ jẹ gbadun B'igba ba yi pẹnrẹn gbogbo wọn a sa lọ o Ilara ti pọju, ikorira ti pọju Ko le silọsiwaju ninu abosi Ikunsinu ti pọju atimọtẹni nikan Ko le silọsiwaju ninu iwa ibajẹ yii o Ọrẹ otitọ ṣọwọn o Ife otitọ ṣọwọn ye Oo le gbara l'ẹnikankan o Wọn a ba ẹ jẹ o, wọn a ba ẹ mu o To ba yẹyin pada, wọn a sọrọ ẹ ni buruku Wọn a ba ẹ logba, wọn a ba ẹ jẹ gbadun B'igba ba yi pẹnrẹn gbogbo wọn a sa lọ o Ilara ti pọju, ikorira ti pọju Ko le silọsiwaju ninu abosi Ikunsinu ti pọju atimọtẹni nikan Ko le silọsiwaju ninu iwa ibajẹ yii o O-o e-e