Kishore Kumar Hits

Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band - Omoagba şarkı sözleri

Sanatçı: Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band

albüm: Oriojori-Eternal Spirits


Ọmọàgbà, ṣèb'ó ti dé'lé owó o
Má mà ṣe ṣì'wà wù, má jẹ'un wọmù-wọmù bí àlejò
Ye o, ọmọàgbà, à l'o ti wọ'lé ọlá o
Má mà ṣe ṣì'wà wù, má tẹ'lẹ' jàù-jàù bí àjèjì o
Tere, te, re-re

Ẹniábiire kìí bínú òdì
Oníwàtútù, ẹni're ni
Ọmọlúwàbí, abánitọ'mọ o, atúnlù'tò, ọmọ ọkọ, eh, eh
Eh, ọmọàgbà, ṣé bo ti wọlé owó o
Má-mà ṣe ṣì'wà wù, má jẹ'un wọmù-wọmù bí àlejò
Ye o, ọmọàgbà, à l'o ti délé àgbàrá o
Má-mà ṣe ṣì'wà wù, má tẹ'lẹ' jàù-jàù bí àjèjì o

Ẹni è tó fún, wọn ń bẹ l'óde o
Àwọn yẹn ń wo'jú Ọlọ'run l'ókè, Ọba ní
Ẹni ò rí b'átiṣé, bi wọn pọ' ní'ta
Àwọn yẹn ń wo'jú Elédùmarè, kó dáhùn
Ọmọàgbà, aa lo tí wọlé ọlá o
Má-mà ṣe ṣì'wà wù, má jẹ'un wọmù-wọmù bí àlejò
Ye o, ọmọàgbà, à l'o ti délé àgbàrá o
Má mà ṣe ṣì'wà wù, má tẹ'lẹ' jàù-jàù bí o

Ẹni ábiire, kìí bínú òdì
Oníwàtútù, ọmọ ọkọ' ní
Ọmọlúwàbí, abánitọ'mọ o, atúnlù'tò, ẹní 're
Ọmọàgbà, ṣèb'ó ti dé'lé owó o
Má-mà ṣe ṣì'wà wù, má jẹ'un wọmù-wọmù bí àlejò
Ye o, ọmọàgbà, à l'o ti wọ'lé ọlá o
Má-mà ṣe ṣì'wà wù, má tẹ'lẹ' jàù-jàù bí àjèjì o

Má jẹ'un wọmù-wọmù bí àlejò

Má tẹ'lẹ' jàù-jàù bí àjèjì
Ye o, ọmọàgbà

Má jẹ'un wọmù-wọmù bí àlejò

Má tẹ'lẹ' jàù-jàù bí àjèjì
Ye o, ọmọàgbà

Má jẹ'un wọmù-wọmù bí àlejò

Má tẹ'lẹ' jàù-jàù bí àjèjì

Поcмотреть все песни артиста

Sanatçının diğer albümleri

Benzer Sanatçılar