Kishore Kumar Hits

Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band - Orisimeta şarkı sözleri

Sanatçı: Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band

albüm: Huruhara


Orisimeta eda laa pade arinrinajo

Orisimeta eda laa kan l'ode aye eni're
Eni ti o gbe ni soke, iyen a tan bi ojo tuntun
Eni ti o b'eni kedun kii jina si'bi ofo
Eni ti o loso idena, iyen ki ma i f'oju han ni
K'inu re ma so e eni're
K'owo e ma ri're ati ibukun
Ani kori e gbe e de bi ayo, onu ni Baba wi
Ase gun! Be'ni

Orisimeta eda laa pade arinrinajo

Orisimeta eda laa kan l'ode aye eni're
Eni ti o gbe ni pon s'eyin g'oke laikun lai s'awawi
Eni ti o ko ni l'ese bi itakun arapalakiri
Eni ti o wo ni s'ogbun ijogbo, agbara olorikunkun
K'inu re ma so e eni're
K'owo e ma ri're ati ibukun
Ani kori e gbe e de bi ayo, onu ni Baba wi
Ase gun!

Orisimeta eda laa pade arinrinajo
Orisimeta eda laa kan l'ode aye eni're
Eni ti o ba ni so'ro tutu, a fi'nu han ni
Eni ti o to ni s'ona iya, oun ke a gba 'bomiran
Eni ti o ba ni se po, a gb'eyin se yeye eni
K'inu re ma so e eni're
K'owo e ma ri're ati ibukun
Ani kori e gbe e de bi ayo, onu ni Baba wi
Ase gun!

K'inu re ma so e eni're
K'owo e ma ri're ati ibukun
Ani kori e gbe e de bi ayo, oun ni Baba wi
Ase gun!

Ore wa, ore wa
Ma lo jeje
Ase ti gun nani
Malo
Ko si ewu, ko si ewu Lona
Malo, malo jeje, jeje malo

Поcмотреть все песни артиста

Sanatçının diğer albümleri

Benzer Sanatçılar