Kishore Kumar Hits

Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band - Eye Mejila şarkı sözleri

Sanatçı: Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band

albüm: Olumuyiwa


Ẹyẹ méjìlá, l'órí igi, l'étí fèrèsé ilé mi
Wọn mí kọ'rin, l' òwúrọ' tí mo jí
Wọn mí kọ'rin ayọ

Wọn mí kọ'rin ìwúrí
Mo wá gbé'ra ní'lẹ', mo bọ'jú, bọ'nu
Mo gbé àpamọ'wọ' mi, mo kó bàtà s'ẹsẹ
Ojú mà mí ro mí, àárẹ m'ọ'kàn mi
Ẹyẹ ó dá'nu dúró o, wọn mí kọ'rin

Wọn mí kọ'rin ìgboyà

Wọn mí kọ'rin ìṣítí
Wọn ní
"Ṣe gírí, múra jáde, òní mà ládùn púpọ"
Ṣe kíá-kíá, yára bóóde, ire mà mí pè ọ o

Mo ṣí ilẹkùn ilé, mo bọ' s'óde
Mo rìn pàdé ẹbí, pẹ'l'álàdúgbò
Mo fi tẹ'rìtẹ'rìn kí gbogbo wọn

Mo mí kọ'rin ayọ

Mo mí kọ'rin ìwúrí
Mo mà d'óko òwò mi, mo wà ní'bi iṣẹ'
Mo pàdé ọdọ, mo mà r'ọmọdé níbẹ' o, pẹ'l'ágbàlagbà
L'ọ'kùnrin, l'óbìnrin
Mo r'ẹ'ni tí ń ronú, mo r'ẹ'ni tí ń bẹ'rù
Mo r'ẹni tí ń gbọn l'ẹsẹ, t'ó ń ṣiyèméjì
Ma fi sùúrù kẹ wọn, ma tọ wọn s'ọnà

Mo mí kọ'rin ìgboyà

Mo mí kọ'rin ìṣítí
Mo ní
"Ṣe gírí, múra jáde, òní mà ládùn púpọ"
Ṣe kíá-kíá, yára bóóde, ògo mà mí pè wá o

Ẹyẹ méjìlá, l'órí igi, l'étí fèrèsé ilé mi
Wọn mí kọ'rin, l'òwúrọ' tí mo jí
Wọn mí kọ'rin ayọ'

Wọn mí kọ'rin ìwúrí
Wọn ní
"Ṣe gírí, múra jáde, òní mà ládùn púpọ"
Ṣe kíá-kíá, yára bóóde o, ire mà mí pè ọ' o
Ṣe gírí, múra jáde o, òní mà ládùn púpọ
Wọn ni, "Ṣé kíá-kíá, yára bóóde o, ogo wa mí pè wa o"
Wọn ni, "Ṣé gírí, múra jáde, múra jáde o, òní mà ládùn púpọ"
Ṣe kíá-kíá, wọn ni, "Yára bóóde, yára bóóde, ire mà mí pè ọ o"
Wọn ní, wọn ni, "Ṣé gírí, ani o múra jáde, múra jáde, òní mà ládùn púpọ"
Ṣe kíá-kíá, ani o yára bóóde o, ogo wa mí pè wa o
(Ṣégiri) mura jade
Mura jade
Yára bóóde

Поcмотреть все песни артиста

Sanatçının diğer albümleri

Benzer Sanatçılar