Kishore Kumar Hits

Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band - Aimokan şarkı sözleri

Sanatçı: Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band

albüm: Olumuyiwa


Ṣ'ówó ló wùn ọ', t'ó ń wá, t'ó ń sá'ré kìràkìtà?
Àbí 'lé lo fẹ' kọ', tó gùn ọ' l'ọ'kàn, t'ó nbẹ' jàùjàù o?
Kò sí're t'á ńfẹ tí ẹ'dá kò ní rí, b'ásìkò bá tó o
K'á ṣáà ma wù'wà 're, l'ó tọ' o
K'a ṣáà ma wù'wà gidi, ọrẹ'mi, l'áyé

Mo rí ọ t'o gb'ẹ'rù l'órí l'ọ'sán tí òòrùn tàn yanyan
Mo tún rí ọ l'ọ'gànjọ' t'o gbé'un s'éjìká nmí hílàhílo o
Bó ti wù k'ó ti rí, ire ẹ'dá kò ní kọjá rẹ', b'ópẹ', b'óyá o
K'á ṣáà ní sùúrù l'ó tọ' o
K'á ṣáà n'ítẹ'lọ'rùn, ọrẹ mi, l'áyé

Ilara ò l'érè (ilara ò l'érè o), ẹ gbọ' mi, ó ńsọ ni d'èrò ẹ'yìn ni
Òòrùn ò ní ràn títí, títí (ràn títí o) k'ó gba 'ṣẹ' òṣùpá ṣe l'ókè
Ojú ọ'run t'ẹ'yẹ fò lẹ'gbẹgbẹ'rún l'áì f'ara kan'ra o
K'á ṣáà l'áforítì l'ó tọ' o
K'á ṣáà n'íwà tútù, ọ'rẹ' mi, l'áyé
Ṣ'ọgbọn l'ó wùn ọ', t'ó nwá (ọgbọn l'ó wùn ọ'), t'ó nbẹ' gìjàgìjà kiri?
Àbí'yì l'ò nfẹ', kí gbogbo ayé máa wá rìrì fún ẹ o?
Ire ò ní kọjá on'íre, ojú mà níí pẹ' sí o
K'á ṣáà ma wù'wà 're, l'ó to o
K'á ṣáà ma wù'wà gidi, ọrẹ mi, l'áyé
Àìmọ'kan l'ó ń dàmú ẹ'dá o
L'ó ń dàmú ènìyàn, t'ó nṣè'páyà fún ọla
Ìgbà àwa yió l'ádùn gan, yió láyọ púpọ'
K'á ṣáà ma wù'wà 're, l'ó tọ' o
K'á ṣáà ma wù'wà gidi, ọrẹ mi, l'áyé

(Àìmọ'kan l'ó ń dàmú ẹ'dá o)
L'ó ndàmú ènìyàn, t'ó ń ṣè'páyà fún ọ'la
(Ìgbà àwa yió l'ádùn gan) yió láyọ púpọ'
K'á sáà ma wù'wà 're, l'ó tọ' o
(K'á sáà ma wù'wà gidi) ọrẹ mi, l'áyé
(Àìmọ'kan l'ó ń dàmú ẹdá o)
L'ó ń dàmú ènìyàn, t'ó ńṣè'páyà fún ọ'la
(Ìgbà àwa yió l'ádùn gan) yió láyọ púpọ'
K'á ṣáà ma wù'wà 're, l'ó tọ o
(K'á ṣáà ma wù'wà gidi) ọrẹ mi, l'áyé
(Àìmọ'kan l'ó ń dàmú ẹdá o)
L'ó ń dàmú ènìyàn, t'ó ńṣè'páyà fún ọ'la
(Ìgbà àwa yió l'ádùn gan) yió láyọ' púpọ'
K'á ṣáà ma wù'wà 're, l'ó tọ o
(K'á ṣáà ma wù'wà gidi) ọ'rẹ' mi, l'áyé
K'á ṣáà ma wù'wà 're, l'ó tọ o (k'á ṣáà ma wù'wà gidi)
K'á ṣáà ma wù'wà 're, l'ó tọ' o (k'á ṣáà ma wù'wà gidi)
K'á ṣáà ma wù'wà 're, l'ó tọ o

Поcмотреть все песни артиста

Sanatçının diğer albümleri

Benzer Sanatçılar